Amos 1:3-5

Ìdájọ́ àwọn aládùúgbò Israẹli

3 aÈyí ni ohun tí Olúwa wí:

“Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta tí Damasku,
àní fún mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà
Nítorí wọn fi ohun èlò ìpakà pa Gileadi.
Pẹ̀lú ohun èlò irin tí ó ní eyín mímú
4Èmi yóò rán iná sí ilé Hasaeli
Èyí ti yóò jó àwọn ààfin Beni-Hadadi run.
5Èmi yóò ṣẹ́ ọ̀pá ìdábùú Damasku;
Èmi yóò sì pa ọba tí ó wà ní Àfonífojì Afeni run
àti ẹni tí ó di ọ̀pá aládé mú ní Beti-Edeni.
Àwọn ará a Aramu yóò lọ sí ìgbèkùn sí Kiri,”
ni Olúwa wí.
Copyright information for YorBMYO